Leviticus 13:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí alufaa bá yẹ̀ ẹ́ wò, tí irun ọ̀gangan ibẹ̀ kò sì di funfun, tí wúwú tí ó wú kò sì jìn ju awọ ara olúwarẹ̀ lọ, ṣugbọn tí ó wòdú, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi alufa na ba wò o, si kiyesi i, ti irun funfun kò si sí ninu rẹ̀, bi kò ba si jìn jù awọ ara lọ, ti o si dabi ẹni wodú, nigbana ni ki alufa ki o sé e mọ́ ni ijọ́ meje:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí kò sì sí irun funfun níbẹ̀ tí ó sì ti gbẹ: kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.