Leviticus 13:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí alufaa bá yẹ àrùn ẹ̀yi yìí wò, tí kò bá jìn ju awọ ara lọ, tí irun dúdú kò sì hù jáde ninu rẹ̀, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi alufa ba si wò àrun pipa na, si kiyesi i, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju, ti kò si sí irun dudu ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o sé àlarun pipa na mọ́ ni ijọ́ meje:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ egbò yìí wò tí kò sì jinlẹ̀ ju àwọ̀ ara lọ tí kò sì sí irun dúdú kan níbẹ̀. Kí àlùfáà fi ẹni náà pamọ́ fún ọjọ́ méje.