Leviticus 13:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ àrùn ẹ̀yi náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri sí i, tí kò sì jìn ju awọ ara lọ, kí alufaa pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì di mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò pipa na; si kiyesi i bi pipa na kò ba ràn si awọ ara, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju; nigbana ni ki alufa ki o pè e ni mimọ́: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí àlùfáà yẹ làpálàpá náà wò, ní ọjọ́ kéje bí kò bá ràn ká gbogbo àwọ̀ ara: tí kò sì jinlẹ̀ ju inú àwọ̀ ara lọ. Kí àlùfáà pè é ní mímọ́: Kí ó fọ aṣọ rẹ̀: òun yóò sì mọ́.