Leviticus 13:42 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ibi tí ó pá ní orí rẹ̀ tabi iwájú rẹ̀ yìí bá lé, tí ó sì pọ́n, ẹ̀tẹ̀ ni ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí jẹ jáde níbi tí orí tabi iwájú rẹ̀ ti pá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi õju funfun-pupa rusurusu ba mbẹ li ori pipa na, tabi iwaju ori pipa na; ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu pipa ori na, tabi ni pipá iwaju na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ó bá ní egbò pupa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ní ibi orí rẹ̀ tí ó pá, tàbí níwájú orí rẹ̀: àrùn tí ń ràn ká iwájú orí tàbí ibi orí ni èyí.