Leviticus 13:46 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo jẹ́ aláìmọ́, níwọ̀n ìgbà tí àrùn yìí bá wà lára rẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́; òun nìkan ni yóo sì máa dá gbé lẹ́yìn ibùdó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni gbogbo ọjọ́ ti àrun na mbẹ li ara rẹ̀ ni ki o jẹ́ elẽri; alaimọ́ ni: on nikan ni ki o ma gbé; lẹhin ibudó ni ibujoko rẹ̀ yio gbé wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ìgbà tí àrùn náà bá wà ní ara rẹ̀; aláìmọ́ ni: kí ó máa dá gbé. Kí ó máa gbé lẹ́yìn ibùdó.