Leviticus 13:55 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Alufaa yóo tún yẹ ohun èlò tí àrùn náà ràn mọ́ wò lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọ̀ ọ́. Bí ọ̀gangan ibi tí àrùn yìí ràn mọ́ kò bá mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tàn káàkiri sí i; sibẹ kò mọ́; jíjó ni ó níláti jó o níná, kì báà jẹ́ iwájú, tabi ẹ̀yìn aṣọ tabi awọ náà ni àrùn ràn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki alufa ki o si wò àrun na, lẹhin igbati a fọ̀ ọ tán: si kiyesi i, bi àrun na kò ba pa awọ rẹ̀ dà, ti àrun na kò si ràn si i, alaimọ́ ni; ninu iná ni ki iwọ ki o sun u; o kẹ̀ ninu, iba gbo ninu tabi lode.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn tí ẹ bá ti fọ ohun ti ẹ̀tẹ̀ náà mú tan, kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò: bí ẹ̀tẹ̀ náà kò bá yí àwọn aṣọ náà padà, bí kò tilẹ̀ tí ì ràn: Àìmọ́ ni ó jẹ́. Ẹ fi iná sun un, yálà ẹ̀gbẹ́ kan tàbí òmíràn ní ẹ̀tẹ̀ náà dé.