Leviticus 13:57 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó bá tún jẹ jáde lára ẹ̀wù, tabi lára aṣọ, tabi ohun èlò aláwọ náà, a jẹ́ pé ó bẹ̀rẹ̀ sí tàn káàkiri nìyí, jíjó ni kí ó jó ohun èlò náà níná.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si hàn sibẹ̀ ninu aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe, àrun riràn ni: ki iwọ ki o fi iná sun ohun ti àrun na wà ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ó bá tún ń farahàn níbi aṣọ náà, lára aṣọ títa náà, lára aṣọ híhun náà tàbí lára ohun èlò awọ náà, èyí fi hàn pé ó ń ràn ká. Gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà bá wà lára rẹ̀ ni kí ẹ fí iná sun.