Leviticus 14:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú ọ̀dọ́ àgbò meji tí kò lábàwọ́n, ati ọ̀dọ́ abo aguntan ọlọ́dún kan tí kò lábàwọ́n, ati ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, tí a fi òróró pò ati ìwọ̀n ìgò òróró kan fún ẹbọ ohun jíjẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni ijọ́ kẹjọ ki o mú ọdọ-agutan meji akọ alailabùku wá, ati ọdọ-agutan kan abo ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa mẹta òṣuwọn deali iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati òṣuwọn logu oróro kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ọjọ́ kejọ kí ó mú àgbò méjì àti abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pò pọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n òróró kan.