Leviticus 14:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Òfin tí ó jẹmọ́ ti ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ adẹ́tẹ̀ nìyí: kí wọ́n mú adẹ́tẹ̀ náà wá sí ọ̀dọ̀ alufaa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ni yio ma ṣe ofin adẹ́tẹ li ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀: ki a mú u tọ̀ alufa wá:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú-un tọ àlùfáà wá.