Leviticus 14:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí alufaa pàṣẹ pé kí wọn kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà jáde, kí ó tó lọ yẹ àrùn náà wò; kí ó má baà pe gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé náà ní aláìmọ́; lẹ́yìn náà, kí alufaa lọ wo ilé náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki alufa ki o fun wọn li aṣẹ, ki nwọn ki o kó ohun ile na jade, ki alufa ki o to wọ̀ inu rẹ̀ lọ lati wò àrun na, ki ohun gbogbo ti mbẹ ninu ile na ki o máṣe jẹ́ alaimọ́: lẹhin eyinì ni ki alufa ki o wọ̀ ọ lati wò ile na:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má báà di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò.