Leviticus 14:48 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣugbọn bí alufaa bá wá yẹ ilé náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri lára ògiri rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti tún un rẹ́, alufaa yóo pe ilé náà ní mímọ́, nítorí àrùn náà ti san.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati bi alufa ba wọ̀ ile, ti o si wò o, si kiyesi i, ti àrun inu ile na kò ba ràn si i, lẹhin igbati a rẹ́ ile na tán; nigbana ni ki alufa ki o pè ile na ni mimọ́, nitoripe àrun na ti jiná.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí àlùfáà bá wá yẹ̀ ẹ́ wò tí àrùn náà kò gbilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tí a ti rẹ́ ilé náà: kí àlùfáà pe ilé náà ní mímọ́, torí pé àrùn náà ti lọ.