Leviticus 14:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó fá irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo wá sí ibùdó, ṣugbọn ẹ̀yìn àgọ́ rẹ̀ ni yóo máa gbé fún ọjọ́ meje.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje.