Leviticus 14:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ keje yóo fá irun orí rẹ̀, ati irùngbọ̀n rẹ̀, ati irun ìpéǹpéjú rẹ̀ ati gbogbo irun ara rẹ̀ patapata, yóo fọ gbogbo aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe ni ijọ́ keje, ni ki o fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro li ori rẹ̀, ati irungbọn rẹ̀, ati ipenpeju rẹ̀, ani gbogbo irun rẹ̀ ni ki o fá kuro: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ pẹlu ninu omi, on o si di mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ kéje: irun orí rẹ̀, irungbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tó kù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.