Leviticus 15:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kan ohunkohun, ninu ohun tí ó fi jókòó di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ru èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí ẹni náà fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; olúwarẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o wà nisalẹ rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ati ẹniti o rù ohun kan ninu nkan wọnni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó wà lábẹ́ ọkùnrin náà di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ ara rẹ̀. Yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.