Leviticus 15:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí nǹkan ọkunrin dà lára rẹ̀ yìí gbọdọ̀ fọ ọwọ́ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ẹni náà bá fi ọwọ́ kàn, kí ó tó fọ ọwọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹnikẹni ti ẹniti o ní isun ba farakàn, ti kò ti wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ ninu omi, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ọkùnrin tí ó ní ìṣunjáde ní ara rẹ̀ bá farakàn láì fi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.