Leviticus 15:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí wọ́n bá sọ ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí di mímọ́ kúrò ninu ohun tí ó dà lára rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ meje fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ ninu odò tí ó ń ṣàn; yóo sì di mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ẹniti o ní isun ba si di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, fun isọdimimọ́ rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi ti nṣàn, yio si jẹ́ mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí a bá wẹ̀ nù kúrò nínú ìṣunjáde rẹ̀ gbọdọ̀ ka ọjọ́ méje fún àwọn ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́: kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀: yóò sì di mímọ́.