Leviticus 15:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára obinrin fún ọpọlọpọ ọjọ́, tí kì í sì í ṣe àkókò nǹkan oṣù rẹ̀, tabi tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá dà kọjá iye ọjọ́ tí ó yẹ kí ó dà, ó jẹ́ aláìmọ́ ní gbogbo àkókò tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lára rẹ̀. Yóo jẹ́ aláìmọ́ bí ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati bi obinrin kan ba ní isun ẹ̀jẹ li ọjọ́ pupọ̀ le ìgba ìyasapakan rẹ̀; tabi bi o ba si sun rekọja ìgba ìyasapakan rẹ̀; gbogbo ọjọ́ isun aimọ́ rẹ̀ yio si ri bi ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀: o jẹ́ alaimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí obìnrin bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀ yálà sí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tàbí tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá kọjá ìgbà tí ó yẹ. Gbogbo ìgbà tí ó bá fi ń ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà ni yóò fi wà ní àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀.