Leviticus 16:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn láàyè ni yóo fa ẹran tí gègé Asaseli bá mú kalẹ̀ níwájú OLUWA, yóo ṣe ètùtù lórí rẹ̀, yóo sì tú u sílẹ̀, kí ó sá tọ Asaseli lọ ninu aṣálẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ewurẹ ti ìbo mú fun Asaseli on ni ki o múwa lãye siwaju OLUWA, lati fi i ṣètutu, ati ki o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ si ijù fun Asaseli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ewúrẹ́ tí ìbò bá mú gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ ìpààrọ̀ ni a ó mú wá láàyè ṣíwájú OLÚWA láti fi ṣe ètùtù sí i àti láti jẹ́ kí ó lọ lọ́fẹ̀ẹ́, sí ihà.