Leviticus 16:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, yóo mú ẹ̀yinná láti orí pẹpẹ tí ó wà níwájú OLUWA sinu àwo turari, yóo sì bu turari olóòórùn dídùn tí wọ́n gún, ẹ̀kúnwọ́ meji, yóo sì gbé e lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si mú awo-turari ti o kún fun ẹyin iná lati ori pẹpẹ wá lati iwaju OLUWA, ki ọwọ́ rẹ̀ ki o si kún fun turari didùn ti a gún kunná, ki o si mú u wá sinu aṣọ-ikele:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò sì mú àwo tùràrí tí ó kún fún èédú tí a ti sun pẹ̀lú iná láti orí pẹpẹ wá ṣíwájú OLÚWA: àti ẹ̀kúnwọ́ méjì tùràrí tí a gún kúnná yóò sì mú un wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa.