Leviticus 16:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Lẹ́yìn náà yóo pa ewúrẹ́ ìrúbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn eniyan Israẹli, yóo sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sinu ibi tí aṣọ ìbòjú wà, yóo sì ṣe é bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ mààlúù, yóo wọ́n ọn siwaju ìbòrí ìtẹ́ àánú, yóo sì tún wọ́n ọn siwaju Àpótí Ẹ̀rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ki o pa ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, eyiti iṣe ti awọn enia, ki o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu aṣọ-ikele, ki o si fi ẹ̀jẹ na ṣe bi o ti fi ẹ̀jẹ akọmalu ṣe, ki o si fi wọ́n ori itẹ̀-ãnu, ati niwaju itẹ́-ãnu:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà yìí ni yóò pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà fún àwọn ènìyàn yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa, bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà ni yóò ṣe ti ewúrẹ́ yìí, yóò sì wọ́n ọn sórí ìtẹ́ ètùtù àti ṣíwájú ìtẹ́ ètùtù.