Leviticus 16:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òbúkọ náà yóo sì fi orí rẹ̀ ru gbogbo àìṣedéédé wọn, títí tí ẹni náà yóo fi fà á dé ibi tí eniyan kì í gbé, ibẹ̀ ni yóo ti sọ ọ́ sílẹ̀ kí ó lè wọ inú aṣálẹ̀ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ewurẹ na ki o si rù gbogbo aiṣedede wọn lori rẹ̀ lọ si ilẹ ti a kò tẹ̀dó: ki o si jọwọ ewurẹ na lọwọ lọ sinu ijù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedédé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì tú ewúrẹ́ náà sílẹ̀ ní àṣálẹ́.