Leviticus 16:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo wẹ̀ ní ibi mímọ́, yóo kó àwọn aṣọ tirẹ̀ wọ̀, yóo sì jáde. Lẹ́yìn náà yóo rú ẹbọ sísun tirẹ̀ ati ẹbọ sísun ti àwọn eniyan náà, yóo sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ ati fún àwọn eniyan náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si fi omi wẹ̀ ara rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan, ki o si mú aṣọ rẹ̀ wọ̀, ki o si jade wá, ki o si ru ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ sisun awọn enia, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀ ati fun awọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan: yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú: yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn: