Leviticus 16:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, wọn yóo gbé òkú akọ mààlúù ati ti òbúkọ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹ̀jẹ̀ wọn tí wọ́n gbé wọ ibi mímọ́ lọ láti fi ṣe ètùtù, wọn yóo rù wọ́n jáde kúrò ní ibùdó, wọn yóo sì dáná sun ati awọ, ati ara ẹran ati nǹkan inú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ewurẹ nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹ̀jẹ eyiti a múwa lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ni ki ẹnikan ki o mú jade lọ sẹhin ode ibudó; ki nwọn ki o si sun awọ wọn, ati ẹran wọn, ati igbẹ́ wọn ninu iná.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí ibi mímọ́ jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà.