Leviticus 16:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ohun tí yóo ṣe, nígbà tí yóo bá wọ ibi mímọ́ náà nìyí: kí ó mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan lọ́wọ́ fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan fún ẹbọ sísun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni ki Aaroni ki o ma wá sinu ibi mimọ́: pẹlu ẹgbọrọ akọmalu fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo fun ẹbọ sisun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni Árónì yóò ṣe máa wá sí ibi mímọ́ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun.