Leviticus 16:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Alufaa tí wọ́n bá ta òróró sí lórí, tí wọ́n sì yà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí alufaa àgbà ní ipò baba rẹ̀ ni kí ó máa ṣe ètùtù, kí ó sì máa wọ aṣọ mímọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati alufa na, ẹniti a o ta oróro si li ori, ati ẹniti a o yàsimimọ́ si iṣẹ-alufa dipò baba rẹ̀, on ni ki o ṣètutu na, ki o si mú aṣọ ọ̀gbọ wọnni wọ̀, ani aṣọ mimọ́ wọnni:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà náà tí a ti fí òróró yàn tí a sì ti sọ di mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ilé ìsìn nípò bàbá rẹ̀: òun ni kí ó ṣe ètùtù: yóò sì wọ aṣọ funfun gbòò àní aṣọ mímọ́ náà: òun yóò sì ṣe ètùtù.