Leviticus 17:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn bá jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi OLUWA yóo bínú sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti o ba jẹ ẹ̀jẹkẹjẹ; ani emi o kọ oju mi si ọkàn na ti o jẹ ẹ̀jẹ, emi o si ke e kuro ninu awọn enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Ísírẹ́lì tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrin wọn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀: èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.