Leviticus 17:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli, tabi àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin wọn tí ó bá lọ ṣe ọdẹ tí ó sì pa ẹran tabi ẹyẹ tí eniyan lè jẹ, ó níláti ro gbogbo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì wa erùpẹ̀ bò ó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti nṣe ọdẹ ti o si mú ẹranko tabi ẹiyẹ ti a ba jẹ; ani ki o ro ẹ̀jẹ rẹ̀ dànu, ki o si fi erupẹ bò o.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí àlejò tí ń gbé láàrin wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀.