Leviticus 17:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí gbogbo ohun alààyè wà, nítorí náà ni mo fi sọ fún ẹ̀yin ọmọ Israẹli pé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá alààyè kankan, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè gbogbo wà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́, a óo yọ ọ́ kúrò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe ẹmi gbogbo ara ni, ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ẹmi rẹ̀: nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ ẹrankẹran: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi ara gbogbo: ẹnikẹni ti o ba jẹ ẹ li a o ke kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan: torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà: ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.