Leviticus 17:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì jẹ ohunkohun tí ó kú fúnra rẹ̀, tabi tí ẹranko burúkú fà ya, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn ìgbà náà ni yóo tó pada di mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo ọkàn ti o ba jẹ ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, tabi eyiti a fàya, iba ṣe ọkan ninu awọn ibilẹ, tabi alejò, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: nigbana li on o mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnrarẹ̀: tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò: ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀: yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́.