Leviticus 17:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
tí kò bá mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún OLUWA níwájú Àgọ́ mímọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ yóo jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀, ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u li ẹbọ wi OLUWA niwaju agọ́ OLUWA: a o kà ẹ̀jẹ si ọkunrin na lọrùn, o ta ẹ̀jẹ silẹ; ọkunrin na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí OLÚWA níwájú àgọ́ ìpàdé: ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.