Leviticus 17:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA pa àṣẹ yìí kí àwọn ọmọ Israẹli lè máa mú ẹran ìrúbọ tí wọ́n bá pa ninu pápá wá fún OLUWA, kí wọn mú un tọ alufaa wá lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí wọn sì pa á láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori idí eyi pe, ki awọn ọmọ Israeli ki o le ma mú ẹbọ wọn wá, ti nwọn ru ni oko gbangba, ani ki nwọn ki o le mú u tọ̀ OLUWA wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, sọdọ alufa, ki o si ru wọn li ẹbọ alafia si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú OLÚWA: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá ṣíwájú àlùfáà àní sí OLÚWA ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé: kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí OLÚWA.