Leviticus 17:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí àwọn ọmọ Israẹli má baà tún máa fi ẹran wọn rúbọ sí oriṣa bí wọ́n ti ń ṣe rí. Òfin yìí wà fún arọmọdọmọ wọn títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn ki o má si ṣe ru ẹbọ wọn si obukọ mọ́, ti nwọn ti ntọ̀ lẹhin ṣe àgbere. Eyi ni yio ma ṣe ìlana lailai fun wọn ni iran-iran wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Torí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbérè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.