Leviticus 18:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O kò gbọdọ̀ bá ọmọ ọmọ rẹ lobinrin lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ obinrin tabi ọmọ ọmọ rẹ ọkunrin, nítorí ohun ìtìjú ni ó jẹ́ fún ọ, nítorí pé, ìhòòhò wọn jẹ́ ìhòòhò rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ìhoho ọmọbinrin ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ti ọmọbinrin ọmọ rẹ obinrin, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú: nitoripe ìhoho ara rẹ ni nwọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòòhò wọn, ìhòòhò ìwọ fúnrarẹ ni.