Leviticus 18:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O kò gbọdọ̀ bá obinrin kan lòpọ̀ tán, kí o tún bá ọmọ rẹ̀ obinrin lòpọ̀ tabi ọmọ ọmọ rẹ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi ọmọ ọmọ rẹ̀ obinrin, nítorí pé, ẹbí rẹ̀ ni wọ́n jẹ́, ìwà burúkú ni èyí jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho obinrin ati ti ọmọbinrin rẹ̀; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ obinrin, lati tú ìhoho wọn; nitoripe ibatan ni nwọn: ohun buburu ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Má ṣe bá ìyá àti ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin ọmọbìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan rẹ tímọ́tímọ́ ni: nítorí àbùkù ni.