Leviticus 19:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
O kò gbọdọ̀ kórè gbogbo àjàrà rẹ tán patapata, o kò sì gbọdọ̀ ṣa àwọn èso tí ó bá rẹ̀ sílẹ̀ ninu ọgbà àjàrà rẹ, o níláti fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò si gbọdọ pèṣẹ́ ọgbà-àjara rẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ká gbogbo àjara ọgbà-àjara rẹ; ki iwọ ki o fi wọn silẹ fun awọn talaka ati alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátapáta, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú oko àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.