Leviticus 19:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ kò gbọdọ̀ dájọ́ èké, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka tabi ọlọ́rọ̀, ṣugbọn ẹ gbọdọ̀ máa dá ẹjọ́ àwọn aládùúgbò yín pẹlu òdodo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ: iwọ kò gbọdọ gbè talaka, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe ojusaju alagbara: li ododo ni ki iwọ ki o mã ṣe idajọ ẹnikeji rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúṣàájú sí ẹjọ́ talákà: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn: ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ.