Leviticus 19:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ọkunrin kan bá bá ẹrubinrin tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ẹlòmíràn lòpọ̀, tí wọn kò bá tíì ra ẹrubinrin náà pada, tabi kí wọ́n fún un ní òmìnira rẹ̀, kí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ náà, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ tìtorí pé ẹrú ni kí wọn pa wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹnikẹni ti o ba bá obinrin dàpọ, ti iṣe ẹrú, ti a fẹ́ fun ọkọ, ti a kò ti ràpada rára, ti a kò ti sọ di omnira; ọ̀ran ìna ni; ki a máṣe pa wọn, nitoriti obinrin na ki iṣe omnira.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tíì di òmìnira.

Recommended Reading