Leviticus 19:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, tí ẹ bá sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso fún jíjẹ, ẹ ka gbogbo èso tí wọ́n bá so fún ọdún mẹta ti àkọ́kọ́ sí aláìmọ́; èèwọ̀ ni, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nigbati ẹnyin o ba si dé ilẹ na, ti ẹnyin o si gbìn onirũru igi fun onjẹ, nigbana ni ki ẹnyin kà eso rẹ̀ si alaikọlà: li ọdún mẹta ni ki o jasi bi alaikọlà fun nyin; ki a máṣe jẹ ẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn bí ohun èèwọ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ jẹ ẹ́