Leviticus 19:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ kò gbọdọ̀ kó ọ̀rọ̀ yín lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláyẹ̀wò tabi àwọn abókùúsọ̀rọ̀, kí wọ́n má baà sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Máṣe yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe wá ajẹ́ kiri, lati fi wọn bà ara nyin jẹ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ẹ má ṣe tọ abókúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.