Leviticus 2:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹbọ ohun jíjẹ tí o bá mú wá fún OLUWA kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà ninu, nítorí pé ìwúkàrà tabi oyin kò gbọdọ̀ sí ninu ẹbọ sísun sí OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A kò gbọdọ fi iwukàra ṣe gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti ẹnyin o mú tọ̀ OLUWA wá: nitori ẹnyin kò gbọdọ sun iwukàra, tabi: oyinkoyin, ninu ọrẹ-ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ tí ẹ bá mú wá fún OLÚWA kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà nínú, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ sun ohun wíwú tàbí oyin nínú ọrẹ tí ẹ fi iná sun sí OLÚWA.