Leviticus 2:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ẹbọ ohun jíjẹ rẹ ni o gbọdọ̀ fi iyọ̀ sí, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí iyọ̀ wọ́n ninu ọrẹ ohun jíjẹ rẹ; nítorí pé iyọ̀ ni ẹ̀rí majẹmu láàrin ìwọ pẹlu Ọlọrun rẹ, o níláti máa fi iyọ̀ sí gbogbo ẹbọ rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ dùn; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ ki iyọ̀ majẹmu Ọlọrun rẹ ki o má sí ninu ẹbọ ohunjijẹ rẹ: gbogbo ọrẹ-ẹbọ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ yín. Ẹ má se aláì fi iyọ̀ májẹ̀mu Ọlọ́run yín sínú àwọn ọrẹ ohun jíjẹ yín, ẹ fi iyọ̀ sí gbogbo ọrẹ yín.