Leviticus 2:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Alufaa yóo bù ninu ọkà pípa ati òróró náà, pẹlu gbogbo turari orí rẹ̀, yóo sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ìrántí. Ẹbọ sísun sí OLUWA ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki alufa ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀, apakan ninu ọkà gigún rẹ̀, ati apakan ninu oróro rẹ̀, pẹlu gbogbo turari rẹ̀: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà yóò sun ẹbọ ìrántí lára ọkà àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí OLÚWA.