Leviticus 2:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí ó bá jẹ́ pé ohun jíjẹ tí a yan lórí ààrò ni ẹbọ náà, kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu rẹ̀. Ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára tí a fi òróró pò ni wọ́n gbọdọ̀ fi yan án, ó sì lè jẹ́ burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu tí a da òróró lé lórí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwọ ba si mú ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ wá, ti a yan ninu àro, ki o jẹ́ àkara alaiwu iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, tabi àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ, èyí tí a yan lórí ààrò iná, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúná dáradára, àkàrà tí a se láì ní ìwúkàrà, tí a sì fi òróró pò àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ṣe láì ní ìwúkàrà èyí tí a fi òróró pò.