Leviticus 20:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹnìkan bá fẹ́ iyawo, tí ó sì tún fẹ́ ìyá iyawo náà pẹlu, ìwà burúkú ni; sísun ni kí wọ́n sun wọ́n níná, ati ọkunrin ati àwọn obinrin mejeeji, kí ìwà burúkú má baà wà láàrin yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ọkunrin ti o ba fẹ́ obinrin ati iya rẹ̀, ìwabuburu ni: iná li a o fi sun wọn, ati on ati awọn; ki ìwabuburu ki o má ṣe sí lãrin nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyatọmọ papọ̀: ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má baà gbilẹ̀ láàrin yín.