Leviticus 20:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí ọkunrin kan bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ baba rẹ̀ tabi ọmọ ìyá rẹ̀, tí wọ́n sì rí ìhòòhò ara wọn, ohun ìtìjú ni; lílé ni kí wọ́n lé wọn jáde kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn, nítorí pé ó ti bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀. Orí rẹ̀ ni yóo sì fi ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati bi ọkunrin kan ba fẹ́ arabinrin rẹ̀, ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀, ti o si ri ìhoho rẹ̀, ti on si ri ìhoho rẹ̀; ohun buburu ni; a o si ke wọn kuro loju awọn enia wọn: o tú ìhoho arabinrin rẹ̀; on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin bàbá rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí: Ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn: ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀. Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀.