Leviticus 20:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ, tabi arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ìwà ìbàjẹ́ ni láàrin ẹbí. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ kò si gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ, tabi ti arabinrin baba rẹ: nitoripe o tú ìhoho ibatan rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Má ṣe bá arábìnrin bàbá tàbí ti ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí o ti tú ìhòòhò ìbátan rẹ: Ẹ̀yin méjèèjì ni yóò ru ẹ̀bi yín.