Leviticus 20:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn ati àwọn àlejò, tí wọn ń ṣe àtìpó ní ààrin wọn tí ó bá fi èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, pípa ni kí wọ́n pa á; kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ni Israeli, ti o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki; pipa ni ki a pa a: ki awọn enia ilẹ na ki o sọ ọ li okuta pa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Ísírẹ́lì tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrin Ísírẹ́lì, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún mólékì, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.