Leviticus 20:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn mo ti ṣèlérí fun yín pé, ẹ̀yin ni ẹ ó jogún ilẹ̀ wọn, n óo fi ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, tí ó sì ń ṣàn fún wàrà ati oyin fun yín, gẹ́gẹ́ bí ohun ìní. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi ti wi fun nyin pe, Ẹnyin o ní ilẹ wọn, ati pe emi o fi i fun nyin lati ní i, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, “Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn; Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin.” Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn yòókù.