Leviticus 20:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ níláti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn ẹran tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́; ati láàrin àwọn ẹyẹ tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹyẹ tabi ẹranko kankan tabi àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri lórí ilẹ̀, tí mo ti yà sọ́tọ̀ fun yín pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ki ẹnyin ki o fi ìyatọ sãrin ẹranko mimọ́ ati alaimọ́, ati sãrin ẹiyẹ alaimọ́ ati mimọ́: ki ẹnyin ki o má si ṣe fi ẹranko, tabi ẹiyẹ, tabi ohunkohun alãye kan ti nrakò lori ilẹ, ti mo ti yàsọ̀tọ fun nyin bi alaimọ́, sọ ọkàn nyin di irira.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrin ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Láàrin ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀: èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́.