Leviticus 20:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èmi gan-an yóo kẹ̀yìn sí olúwarẹ̀, n óo sì yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀; nítorí pé ó ti fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ fún oriṣa Moleki, ó sì ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, ati pé ó ti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si kọju mi si ọkunrin na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀; nitoriti o fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, lati sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, ati lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi tìkarami yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà mólékì ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú.